Nàìjíríà jẹ́ Orílẹ̀-èdè Olómìnira Ìjọba Àpapọ̀ ilẹ̀ Nàìjíríà (Nigeria ni èdè Gẹ̀ẹ́sì) jẹ́ orílẹ̀-èdè ìjọba àpapọ̀ olómìnira tí ó ní ìjọba ìpínlẹ̀ mẹ́rindínlógójì tó fi mọ́ Agbẹ̀gbẹ̀ Olúìlú Ìjọba Àpapọ̀. Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà wà ní apá Iwọ̀ Oòrùn ilẹ̀ Áfríkà. Orílẹ̀-èdè yí pààlà pẹ̀lú orílẹ̀-èdè Benin ní apá ìwọ̀ Oòrùn, ó tún pààlà pẹ́lú orílẹ̀-èdè olómìnira ti Nijẹr ní apá àríwá, Chad àti Kamẹróòn ní apá ìlà Oòrùn àti Òkun Atlantiki ni apá gúúsù. Abuja ni ó jẹ́ Olú-Ìlú fún orílẹ̀-èdè náà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Nàìjíríà ní ẹ̀yà púpọ̀, àwọn ẹ̀yà mẹ́ta ni wọ́n hànde tí wọ́n tóbi jùlọ, tí Wọ́n sì pọ̀ jùlo, tí a sì kó àwọn ẹ̀ka ìsọ̀rí ìsọ̀rí èyà tókù sí abẹ́ wọn. Àwọn wọ̀nyí ni HausaẸ̀yà , Ẹ̀ya Ìgbò ati Yorùbá.
Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní ìtàn fífẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni ẹ̀rí ìmọ̀-aíyejọ́un fihàn pé àwọn ìgbé ènìyàn ní agbègbè ibẹ̀ lọ sẹ́yìn dé kéré pátápátá ọdún 9000 kJ. Agbegbe Benue-Cross River jẹ́ rírò gẹ́gẹ́ bí ile àkókó àwọn Bantu arókèrè ti wón fan ka kiri opo arin àti apágúúsù Áfríkà bí irú omi ní arin ẹgbẹ̀rúndún akoko kJ àti ẹgbẹ̀rúndún kejì.
Orúkọ Nàìjíríà wá láti Odò Ọya, tí a tún mọ̀ gẹ́gẹ́ bíi Odò Náíjà, èyí tó sàn gba Nàìjíríà kọjá. Flora Shaw, tí yíò jẹ́ ìyàwó lọ́jọ́ wájú fún Baron Lugard ará Britan tó jẹ́ alámójútó àmúsìn, ló sẹ̀dá orúkọ yìí ní òpin ọdún 19sa.
Nàìjíríà ni orílẹ̀-èdè tó ní èèyàn púpò jùlọ ní Ilẹ̀ Aláwọ̀dúdú, ikejo ni agbaye, bẹ́ẹ̀ sì ni ó jẹ́ orílẹ̀-èdè tó ní àwọn eniyan alawodudu jùlọ láyé. Ó wà lára àwọn orílẹ̀-èdè tí a ń pè ní "Next Eleven" nítorí okòwò wọn, ó sì tún jẹ́ ọ̀kan nínú Ajoni awon Ibinibi. Okòwò ilẹ̀ Nàìjíríà jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn èyí tó ń dàgbà kíákíá jùlọ lágbàáyé pẹ̀lú IMF tó ń gbèrò ìdàgbàsókè 9% fún 2008 àti 8.3% fún 2009. Ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 2000 sókè, ogunlọ́gọ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà gbé pẹ̀lú iye tó dín ní US$ 1.25 (PPP) lójúmọ́.Nàìjíríà ní okòwò rẹ̀ tóbi jùlọ ní Áfíríkà, ati alágbára ní agbègbè Iwoorun Afirika.
Notice :
This app is develop for education and research purpose with fair use law is apply under creative common license and does not violate the policy about Google-served ads on screens with replicated content .Fair use is a doctrine law that permits limited use of copyrighted material without having to first acquire permission from the copyright holder for education and research purpose .